Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 22: Ẹ Yìn Olúwa

O Praise Ye The Lord

Ẹ yìn Olúwa!
Ẹ yín-In l' ór' òkè;
Ẹ yọ̀ nín' ọ̀rọ̀ Rẹ̀,
Ángẹ́lì 'mọ́lẹ̀;
Ẹ̀yin ọ̀run, gbé E ga;
Ẹni t' ó dá yín,
Wolé k' ẹ sìn Ẹni
N' gbé 'nú ìmọ́lẹ̀.

Ẹ yìn Olúwa!
Ẹ yín-In l' ór' ilẹ̀;
Pẹ̀l' orin ìyìn;
Ọmọ àtúnbí
Yìn Ẹni f' oòr'-ọ̀fẹ́
Fún yín lát' òkè,
Yin Eni t' ó kó yín
L' orin ìfẹ́ Rẹ̀.

Ẹ yìn Olúwa!
Ẹ̀yin t' ẹ̀ẹ́ l' ohùn;
Tún orin ayọ̀
Kọ kárí ayé;
Jẹ́ kí dùùrù gbé 'rìn
Sọ pẹ̀l' ohùn 'jìnlẹ̀
Kí háàpù pẹ̀lú jẹ́wọ́
Iṣẹ́ yanu Rẹ̀.

Ẹ yìn Olúwa!
Jẹ́ k' á fi orin
Àt' ọpẹ́ wa fún Un;
Kí gbogbo wa yín-In;
Fún 'fẹ́ t' Ó fi dá wa
F' àtúnṣe ọ̀run,
Fún, oòr'-ọ̀fẹ́ 'gbàlà
Ẹ yìn Olúwa!