Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 219: Ó Fẹ́ Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹrù Ẹ̀ṣẹ̀ Ẹ

Would You be Free from The Burden of Sin

Ó fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ?
Agbára wà n' ínú ẹ̀jẹ̀ Jésù;
O hà ń fẹ́ ìṣẹ́gun lórí ẹ̀ṣẹ̀?
Agbára wà n' ínú ẹ̀jẹ̀ Rẹ.

Agbára wà, Agbára ńlá wà
N' 'nú ẹ̀jẹ̀ Ọd' àgùntàn;
Agbára wà, agbára ńlá wà
Nínú ẹ̀jẹ̀ Ọd' àgùntàn.

Ó fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìwà ìpá rẹ?
Agbára wà n' 'nú ẹ̀jẹ̀ Jésù
Wá s' òkè Kalfarì fún ìwòsàn,
Agbára wà n' 'nú ẹ̀jẹ̀ Rẹ.

Agbára wà, Agbára ńlá wà
N' 'nú ẹ̀jẹ̀ Ọd' àgùntàn;
Agbára wà, agbára ńlá wà
Nínú ẹ̀jẹ̀ Ọd' àgùntàn.

Ìwọ hà fẹ́ sìn Jésù Ọba rẹ?
Agbára wà nínú ẹ̀jẹ̀ Rẹ:
Ìwọ hà fẹ́ gbé orin yìn Rẹ̀ ga?
Agbára wà n' 'nú ẹ̀jẹ̀ Rẹ.

Agbára wà, Agbára ńlá wà
N' 'nú ẹ̀jẹ̀ Ọd' àgùntàn;
Agbára wà, agbára ńlá wà
Nínú ẹ̀jẹ̀ Ọd' àgùntàn.