Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 218: Ìpè 'Hìnrere Dún Kìkan

The Gospel Trumpet Sounds Today

Ìpè 'hìnrere dún kìkan
L' ohùn ìkìlọ̀ lónìí,
Ìhìnrere bíbọ̀ Jésù
Ń dún káàkírí 'bi gbogbo;
Ó ń sọ f' ọkàn t' ó ń dàkú pé
K' ó jí, k' ó kọ 'rìn ògó,
Ẹ kí ọjọ́ ayọ̀ náà t' ó
Fi ópín sí 'pọ̀njú wa.
Ẹ kí ọjọ́ náà t' ó
Fi ópín sí 'pọ̀njú wa.

Ẹ̀dá ń ké ríróra láti rí,
Ìmọ́lẹ̀ 'gbàlà pípe,
Àwọn Angel ń fi ìrètí
Wò ìlànà ìgbàlà,
Àwa àti àwọn t' ó sùn
Kì yóò ní láti dúró pẹ́,
Láìpẹ́ a ó gun òkè ọ̀run
Láti padé Ọba wa.
Láìpẹ́ a ó gun òkè ọ̀run
Láti padé Ọba wa

Ẹ̀mí ń fi agbára púpọ̀
Fún 'kéde bíbọ̀ Jésù,
T' ó ń sọ fún gbogbo aráyé
Nípa ìpadà Ọba.
"Ìrètí 'bùkún" yìí fún wa
Ní 'tara àt' ìfẹ́ ọkàn;
A ń ké pé, Jésù, wá kánkán
'Tór' ọkàn wa ń fà sí Ọ.
A ń ké pé, Jésù, wá kánkán
'Tór' ọkàn wa ń fà sí Ọ.