Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 216: Jésù Ń Pè Wá Jẹ̀jẹ̀ L' Ohùn Ìfẹ́
Softly And Tenderly Jesus Is Calling
Jésù ń pè wá jẹ̀jẹ̀ l' ohùn ìfẹ́,
Ó ń pè ọ, Ó sì ń pè mí;
L' ẹn' ọ̀nà ọkàn, Ó ń dúró
Ó ń ṣọ́nà. Ó ń retí rẹ àt' èmi.
Máa bọ̀ wá 'lé
Ẹ̀yin aláààrẹ̀ wá 'lé
Pẹ̀lú ìfẹ́ àt' ìtara ni ó ń pè
Wá ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, máa bọ̀.
Kí la ó ṣe dúró nígbà Jésù ń rọ̀ wá
T' Ó ń rọ̀ ọ t' Ó sì ń rọ̀ mí
T' Ó ṣe kò láti gbà ẹ̀bùn àánú Rẹ
Àánú fún ọ àt' èmi
Máa bọ̀ wá 'lé
Ẹ̀yin aláààrẹ̀ wá 'lé
Pẹ̀lú ìfẹ́ àt' ìtara ni ó ń pè
Wá ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, máa bọ̀.
Rò nípa 'fẹ́ 'yànu t' Ó ṣe 'lérí
Ẹ̀bùn fún ọ, àt' èmi;
B' á tilẹ̀ ṣe, síbẹ̀ ìdàríjì wà,
'Dàríjì fún gbogbo wa.
Máa bọ̀ wá 'lé
Ẹ̀yin aláààrẹ̀ wá 'lé
Pẹ̀lú ìfẹ́ àt' ìtara ni ó ń pè
Wá ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, máa bọ̀.