Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 215: Jésù Ń Pè Wá L' Ọ̀sán-àn L' Órù
Jesus Calls Us O'er the Tumult
Jésù ń pè wá l' ọ̀sán-àn l' órù
Láàrín ìrúmí ayé;
L' ọjọ́ojúmọ́ l' a ń gbohùn Rẹ,
Wípé "Kristẹ́n' tẹ̀lé Mi"
Jésù ń pè wá kúrò nínú
Ohun àsán ayé yìí;
Láàrí àfẹ́ ayé, ó ń wí,
Pé Kristẹ́n' ẹ fẹ́ràn Mi.
Láàrín ayọ̀ àt' ẹ̀dùn wa,
Láàrín láálàá oun 'ìróra;
N' ínú 'gbàdùn wa, tàntàn l' Ó ń ké
Pé "Kristẹ́n' ẹ fẹ́ràn Mi."
Olùgbàlà níp' àánú Rẹ
Jẹ́ kí a gbọ́ ìpè Rẹ;
F' etí 'gbọ́ràn fún gbogbo wa,
K' á fẹ́ Ọ jù ayé lọ.