Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 213: Mo L' Olùgbàlà
I Have a Saviour
Mo l' Olùgbàlà t' ó ń bẹ̀bẹ̀
Nín' ògó,
Olùgbàl' ọ̀wọ́n, b' ọ̀rẹ́ ayé kò pọ̀,
Tìfẹ́tìfẹ́ ni Ó ń ṣe àájò lórí mi
Mo fẹ́ k' Olùgbàlà mi sì jẹ́ tire.
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Mo ń gbàdúrà fún ọ.
Mo ní Bàbá; t' Ó fún mi ní ìlérí
Ìrètí àìnípẹ̀kun t' ó ní ìbùkún:
Òun yóò sì pè mí láti padé
Rẹ̀ l' ọ̀run,
A, Òun bá jẹ́ k' èmi mú ọ wá pẹ̀lú!
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Mo ń gbàdúrà fún ọ.
Mo l' agbádá t' ó mọ́ nínú ẹwà rẹ̀,
Ń dúró nín' ògó fún 'yànu mi l' òkè;
N' gbà tí a fi fún mi t' ó ń
dàn n' ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀
Mo fẹ́ k' ìwọ náà rí ọkan gbà pẹ̀lú!
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Mo ń gbàdúrà fún ọ.
Gbà Jésù ti rí ọ, rọ 'tàn náà kalẹ̀,
P' Olùgbàlà mi sì jẹ́ tire pẹ̀lú
Sì máa gbàdúrà kí wọn le
wọ 'nú ògó,
Àdúrà rẹ yóò gbà ó ti gbà fún ọ!
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Fún ọ mo ń gbàdúrà,
Mo ń gbàdúrà fún ọ.