Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 211: Jésù Yóò Gbà Ẹlẹ́ṣẹ̀

Sinners Jesus Will Receive

Jésù yóò gbà ẹlẹ́ṣẹ̀;
Kéde rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá,
Àwọn tí wọ́n ṣako lọ,
Àwọn tí wọ́n ti ṣubú.

Kọ ọ l' orin kọ ọ sì tún un kọ
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Fi òótọ́ náà yé wọn pé:
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀

Wá yóò fún ọ ní sìmí;
Gbà gbọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ dájú;
Yóò gbà ẹni burú jù;
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Kọ ọ l' orin kọ ọ sì tún un kọ
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Fi òótọ́ náà yé wọn pé:
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀

Ọkàn mi dá mi láre
Mo mọ̀ níwájú òfin;
Ẹni t' Ó ti wẹ̀ mi mọ́
Ti san gbogbo gbèsè mi.

Kọ ọ l' orin kọ ọ sì tún un kọ
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Fi òótọ́ náà yé wọn pé:
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀

Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
Àn' èmi t' ó kún f' ẹ̀ṣẹ̀;
Ó ti sọ mi di mímọ́,
Mo bá A wọ 'jọba ọ̀run.

Kọ ọ l' orin kọ ọ sì tún un kọ
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀
Fi òótọ́ náà yé wọn pé:
Krístì ń gbà 'wọn ẹlẹ́ṣẹ̀