Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 210: Ẹnìkan Yóò Gbà 'Bòdè Wọ 'Lé

Someone Will Enter The Pearly Gate

Ẹnìkan yóò gbà 'bòdè wọ 'lé
Nígbòòṣe, Nígbòòṣe,
Yóò tọ̀ ògó t' ó wà níbẹ̀ wò,
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?
Ẹnìkan yóò rìn l' ọ̀nà wúrà,
Yóò rí àwọn ohun t' ó dára,
Yóò rí gbàdùn tá a ti sọ tẹ́lẹ̀;
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?

Ẹnìkan yóò ṣ' èrù rẹ̀ kalẹ̀
Nígbòòṣe, Nígbòòṣe,
Yóò gb' adé nítorí òtítọ́
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?
Ẹnìkan yóò r' Ọba ògó náà.
Yóò gb' adé nítorí òtítọ́
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?
Ẹnìkan yóò r' Ọba ògó náà.
Yóò máa f' ayọ̀ bá A gbé láéláé.
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?

Ẹnìkan yóò wà lẹ́yìn òde
Nígbòòṣe, Nígbòòṣe,
Yóò gb' ohùn kan pé
"N kò mọ̀ ọ rí,"
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?
Ẹnìkan yóò pè láìsí dáhùn,
'Gbà 'lẹ̀kùn bá ti kó s' àtúnṣe
Ẹnìkan yóò gbà ère ìbí,
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?

Ẹnìkan yóò kọ orin ayọ̀
Nígbòòṣe, Nígbòòṣe,
Yóò dàpọ̀ m' ẹgbẹ́ tá a f' ẹ̀jẹ̀ rà;
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?
Ẹnìkan yóò máa kí àwọn,
Àyànfẹ́ tí wọ́n ti ṣáájú lọ,
Yóò wà nín' ògó títí láéláé;
Ìwọ ni bí? Èmi ni bí?