Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 21: Ẹkọrin Títun S' Olúwa

O Sing A New Song To the Lord

Ẹkọrin títun s' Olúwa,
Fún iṣẹ́ 'yanu Rẹ̀;
Ọwọ́ ọ̀tún àt' apá Rẹ̀
L' ó fún wa ní 'ṣẹ́gun.

Jẹ́ k' á kọrin sí Jèhófà,
Pẹ̀lú hárpù àt' ohùn;
Jẹ́ kí ìpè àti fèrè
Pè Olúwa l' ọba.

Jẹ́ k' òkun àt' ẹ̀dá 'nú wọn
'T' ayé 't' ẹ̀dá 'nú rẹ̀,
Odò ṣíṣàn àt' òkè nlá,
P' ohùn pọ̀ yìn Olúwa.

Nítorí pé Olúwa ń bọ̀
Wá ṣe 'dájọ́ ayé;
Yóò f' òdodo ṣe ìdájọ́ o
Àwọn ènìyàn Rẹ̀.