Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 205: Jésù Ń Kọjá Lọ, Jésù Ń Kọjá Lọ
Jesus Is Passing, Jesus Is Passing
Jésù ń kọjá lọ, Jésù ń kọjá lọ,
Wá, ẹ̀yin afọ́jú fún ìríran
Yóò bójú wo yín,
Òun yóò wò yín sàn,
Òun yóò sọ òkùnkùn yín di 'mọ́lẹ̀;
Olùgbàlà yóò fi 'ríran fún yín.
Jésù ń kọjá lọ, Jésù ń kọjá lọ,
Wá, ẹ̀yin àrọ̀ s' ọ̀dọ̀ Olùwòsàn;
Ó kú 'torí yín,
Wọ̀ ọ́ fún ìgbàlà,
Òun yóò fi etí sí ìpè àrọ̀;
Ó ń kọjá, Ó ń kọjá fún gbogbo wa
Jésù ń kọjá lọ, Jésù ń kọjá lọ;
Wá, ẹ̀yin tálákà sí 'bi 'ṣúrà;
Yóò ṣ' amọ̀nà yín,
Yóò sì máa bò yín,
Jésù ń pè yín k' ẹbí má pa yín mọ́;
Wá sí 'bi ọ̀pọ̀ iṣúrà t' ọ̀run.
Jésù ń kọjá lọ, Jésù ń kọjá lọ,
Wá ẹ̀yin t' ẹ̀ṣẹ̀ oun 'tìjú ń dààmú
Ẹ wá, Ó ń bẹ yín,
Jẹ́ k' Ó wò yín sàn,
Gbà t' Ó fi sùúrù pè yín l' orúkọ;
Wá ẹ̀yin t' èrù ẹ̀ṣẹ̀ wọ l' ọ̀run.