Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 204: Agogo Ìhìnrere Ń Lù Lát' Ìlú Dé Ìlú
The Gospel Bells are Ringing
Agogo ìyìnrere
Ń lù lát' ìlú dé ìlú,
'Bùkún àt' ìgbàlà òfẹ̀
Ni wọ́n ń fún ọ àt' èmi,
Ọlọ́run f' aráyé
T' Ó fi Ọmọ Rẹ̀ fún wa,
P' ẹnikẹ́ni tí ó gbà á gbọ́
Yóò n' ìyè àìnípẹ̀kun.
Agogo ìyìnrere
Ń lù lát' ìlú dé ìlú,
Agogo 'ìyìnrere
Ni ń mú ìhìn 'bùkún wá.
Agogo ìyìnrere
Ń pè wá sí àṣẹ ńlá náà,
Jọ̀ọ́ má kọ ìpè Olúwa,
Má sì kọ 'pè oore-ọ̀fẹ́
Àkàrà 'Yè l' Èmi,
Jẹ n' ínú rẹ ọkàn ẹbí,
B' ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pọ́n bí ododo
Wọ́n yóò fún b' ẹ̀gbọ́n owú.
Agogo ìyìnrere
Ń lù lát' ìlú dé ìlú,
Agogo 'ìyìnrere
Ni ń mú ìhìn 'bùkún wá.
Agogo náà máa ń kìlọ̀
B' ó ti ń lù lójòojúmọ́,
Fún àwọn tí ó ń jàfàrà
Nípa ohun t' ó bá wọn.
Ṣ' àsálà f' ẹ̀míi rẹ,
Má dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,
Máṣe b' ojú wò ẹ̀yìn rẹ,
Kí ẹ̀gbẹ́ má ṣe bá ọ.
Agogo ìyìnrere
Ń lù lát' ìlú dé ìlú,
Agogo 'ìyìnrere
Ni ń mú ìhìn 'bùkún wá.
Ayọ̀ ni agogo náà
Fi ń lù káàkírí ayé,
Ó ń sọ nípa ti 'dàríjì
Ti Jésù y' ó fi fún wa,
'Yìnrere t' ayọ̀ ńlá
L' ó mú wá fún gbogbo aráyé
Fún ọ l' a b' Olùgbàlà,
Kríst' Olúwa àt' Ọba.
Agogo ìyìnrere
Ń lù lát' ìlú dé ìlú,
Agogo 'ìyìnrere
Ni ń mú ìhìn 'bùkún wá.