Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 202: Torí Mi Àt' Ìyìnrere Ẹ Lọ Sọ T' Ìràpadà
For My Sake and the Gospel, Go
Torí Mi àt' Ìyìnrere
Ẹ lọ sọ t' Ìràpadà;
Àwọn oníṣẹ́ Rẹ̀ ń ké,
'Àmín! Tire ni gbogbo ògo,'
Wọ́n ń sọ t' ìbí, t' ìyà, t' ikú,
Ìfẹ́ ẹ̀tùtù ńlá Rẹ̀;
Wọ́n ka ohun ayé s' òfo,
F' àjíǹdé oun 'jọba Rẹ̀?
Gbọ́, gbọ́ ìpè ti Jubílì,
Ó ń dún yìí gbogb' ayé ka;
N' ilé àti l' ojú òkun,
A ń tàn ìhìn Ìgbàlà,
Bí ọjọ́ náà ti ń sún mọ́ 'lé,
T' Ogun sì ń gbóná janjan,
Ìmọ́lẹ̀ Ìlà-oòrùn náà
Yóò mọ́ láàárín òkùnkùn.
Síwájú àti síwájú
La ó máa gbọ́ Alélùyà
Ìjọ ajàgùn yóò máa yọ̀,
Pẹ̀l' àwọn okú mímọ́;
A fọ aṣọ wọn n' ínú ẹ̀jẹ̀,
Dùùrù wúrà wọn sì ń dún;
Ayé àt' ọ̀run d' ohùn pọ̀,
Wọ́n ń kọ orin ìṣẹ́gun.
Ó dé Ẹni tá a ń w' ọ̀nà Rẹ̀,
Ẹni ìkẹ̀yìn náà dé,
Immánuẹ́lì tó d' adé
Olúwa àwọn mímọ́,
Ìyè, Ìmọ́lẹ̀ àt' Ìfẹ́,
Mẹ́talọ́kan títí láé;
Tire ni Ìtẹ́ Ọlọ́run
Àti t' Ọdọ́-àgùntàn.