Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 201: Ẹ Máa Lọ Pẹ̀lú Àdúrà
Go Forth on Wings of Faith and Prayer
Ẹ máa lọ pẹ̀lú àdúrà
Ẹ̀yin ìwé mímọ́,
Ẹ ń kéde ìhìn rere ti
Ìgbàlà lát' ọ̀run.
Lọ, ìwọ odì ìránṣẹ́,
Sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé
Irúgbìn ọr' Ọlọ́run wa
L' a kì yóò fún lásán.
Lọ jíṣẹ́ f' àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
Ìkìlọ̀ Ọlọ́run,
F' ọ̀kùn f' ọkàn t' ó rẹ̀wẹ̀sì
Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Lọ, ìwọ odì ìránṣẹ́,
Sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé
Irúgbìn ọr' Ọlọ́run wa
L' a kì yóò fún lásán.
Ṣiṣẹ́ f' aláìbìkítà ẹ̀mí,
Tí kò mọ̀ Ọlọ́run
Rọ̀ wọn láti gb' ẹ̀bùn Ìyè,
Tá a f' ẹ̀jẹ̀ Jésù rà.
Lọ, ìwọ odì ìránṣẹ́,
Sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé
Irúgbìn ọr' Ọlọ́run wa
L' a kì yóò fún lásán.