Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 200: Jésù Ọ̀rọ̀ Rẹ Yé

Lord Thy Word Abideth

Jésù, ọ̀rọ̀ Rẹ yé,
Ó sì ń tọ́ 'ṣiṣẹ́ wa;
Ẹni t' ó bá gbà á gbọ́,
Yóò l' ayọ̀ oùn 'mọ́lẹ̀.

Nígb' ọ̀tá sún mọ́ wa,
Ọ̀rọ̀ Rẹ l' odì wa;
Ọ̀rọ̀ ìtùnú ni,
Ìkó ìgbàlà ni.

B' ìgbì àt' òkùnkùn
Tilẹ̀ bò wa mọ́ 'lẹ̀;
'Mọ́lẹ̀ Rẹ yóò tọ́ọ́ wa,
Yóò sì dáàbò bò wa.

Tani le sọ ayọ̀,
T' ó le kà 'ṣúrà,
Tí ọ̀rọ̀ Rẹ ń fi fún
Ọkàn onírelẹ̀?

Ọ̀rọ̀ àánú, ó ń fi
'Lera fún aláàyè;
Ọ̀rọ̀ ìyè ó ń fi
Ìtùnú f' ẹni ń kú

Àwa ìbá le mọ̀
Ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ ni,
Kí a báà le fẹ́ O,
K' a á sì le sún mọ́ O.