Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 198: Fún Mi Ní Bibel
Give Me the Bible
Fún mi ní Bibel
Ayọ̀ 'ràwọ̀ dídán,
K' ó m' àṣàkó t' ara ń ní láràyá;
Kò s' ìjì t' ó le bò Ìmọ́lẹ̀ dídán,
'Tórí Jésù wá láti gb' àṣàkó.
Fún mi ní Bibel,
ìhìn Mímọ́ dídán
Mọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò tọ́ mi l' ọ̀nà híhà
Ìlànà ìlérí àt' ìfẹ́ papọ̀,
Òòkún yóò d' ìmọ́lẹ̀ ayérayé.
Fún mi ní Bibel,
gbàt' ọkàn bànújẹ́,
Gb' ẹ̀ṣẹ́ àt' ẹ̀dùn mú mi kún f' èrù;
Fún mi l' ọ̀rọ̀ 'yẹbíyẹ̀ tí Jésù sọ,
F' ìgbàgbọ́ hàn pé Jésù wà n' tọ̀sí.
Fún mi ní Bibel,
ìhìn Mímọ́ dídán
Mọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò tọ́ mi l' ọ̀nà híhà
Ìlànà ìlérí àt' ìfẹ́ papọ̀,
Òòkún yóò d' ìmọ́lẹ̀ ayérayé.
Fún mi ní Bibel
k' ó mọ́lẹ̀ s' ọ̀nà mi,
Fi àwọn ewu ayé yìí hàn mi;
Fìtílà t' ó ń jó yóò ṣ' òòkún d' ìmọ́lẹ̀.
Oùn l' ó le f' ọ̀nà àlàáfíà hàn.
Fún mi ní Bibel,
ìhìn Mímọ́ dídán
Mọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò tọ́ mi l' ọ̀nà híhà
Ìlànà ìlérí àt' ìfẹ́ papọ̀,
Òòkún yóò d' ìmọ́lẹ̀ ayérayé.