Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 197: B' Oúnjẹ Ìyè Fún Mi, Olúwa Mi,
Break Thou The Bread Of Life
B' oúnjẹ ìyè fún mi, Olúwa mi,
B' ó ti bù àkàrà lẹ́bá odò:
Nínú ìwé mímọ́, Ni mo ń wá O;
Ọkàn mi ń fà sí O, Ọ̀rọ̀ ìyè!
Búkún òtítọ́ náà Fún mi, Jésù,
Bó O ṣe bùs' àkàrà Ní Galili;
N' gbà náà okò èrú Yóò dòpin,
Èm' ó r' àlàáfíà Rẹ, Olúwa mi.
Ìwọ l' oúnjẹ ìyè, Olúwa mi
Olúwa mi Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Ni yóò gbà mi;
Jẹ́ kí n jẹ nínú Rẹ, Kí n bá O gbé;
Jẹ́ kí n fẹ́ òótọ́ Rẹ, Ìfẹ́ ni O.
Ọ̀rọ̀ 'yè àt' ẹ̀mí L' Ó ń sọ fún mi
Mo fẹ́ gbọ́, ṣùgbọ́n mo j' aláìlera
'Wọ n' Ìrànlọ́wọ́ mi, 'Wọ l' ẹ̀mí mi
Mo ṣẹ́gun nípa ọ̀rọ̀ Mímọ́ Rẹ.