Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 196: Mo Fẹ́ 'Wé Mímọ́ Ọlọ́run
I Love The Sacred Book
Mo fẹ́ 'wé Mímọ́ Ọlọ́run,
Kò s' ìwé t' ó le dípò rẹ̀;
Ó ń tọ́ka mi s' ilé mímọ́,
Ó ń kọ́ mi láti sá f' ewu.
Ìwé Mímọ́! nínú rẹ̀ ni
Mo rí àwòrán Olúwa;
Nínú rẹ̀ ni mo ń kọ́ nípa
Ayọ̀ t' Olúwa le fún ni.
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò dípò Rẹ,
Ìwọ yóò sọ 'fẹ́ Rẹ fún mi;
Èm' ó f' ojú 'gbàgbọ́ kà ọ;
Kí n le pín nín' ayọ̀ t' ọ̀run.
Nín' ìwé rẹ̀ ni mo gbé rí
Àwòkọ Ìf' Ẹlẹ́dàá mi;
Níbẹ̀ n' ìṣúrà ọ̀rọ̀ wà,
Láti kún ọkàn gbogb' ènìyàn.
'Mọ́lẹ̀ ayé, tàn 'mọ́lẹ̀ rẹ,
Láti tọ́ 'ṣiṣẹ́ mi l' ayé;
Jọ̀ọ́ mọ́lẹ̀ s' ọkàn òṣì yìí,
Má sì ṣe jẹ́ kí n ṣìnà lọ.