Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 195: Ẹ̀mí Mímọ́, Aláànú
Gracious Spirit Holy Ghost
Ẹ̀mí Mímọ́, Aláànú,
Ìfẹ́ Rẹ l' a fẹ́ jù n' nú
Àwọn ẹ̀bùn Pentikọst';
Ìfẹ́ Mím' ọ̀run.
Àsán ni 'gbàgbọ́ t' ó le
S' èdè ayé àt' ọ̀run
Àsán ni gbogbo imọ̀,
Láìsí fẹ́ ọ̀run.
Bí mo kú b' ajẹríkú,
Kí n f' iní mi b' òtòsì
Àsán ni bí n kò n' ìfẹ́,
Jọ̀ọ́ fún mi n' ìfẹ́.
'Fẹ́ n' inú 're, ó ń rọjú;
'Fẹ́ ni 'rẹ̀lẹ̀ kì í rò 'bi;
'Fẹ́ l' agbára jù ikú;
Jọ̀ọ́ fún wa n' ìfẹ́.
Gbàgbọ́, 'Rètí, àt' ìfẹ́,
Sọ 'wọ̀ pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀;
Ṣùgbọ́n 'yì t' ó tóbi t' ó
Sì dájú n' ìfẹ́.