Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 194: Olúwa, Mo Gbọ́ Nípa Ojò

Lord I Hear Of Showers Of Blessings

Olúwa, mo gbọ́ nípa ojò
'Bùkún t' Ó ń rọ̀ l' ọ̀fẹ́ẹ́
Ojò ìtùra fún ọkàn,
Jẹ́ k' ó rọ̀ sí orí mi,
Àn' èmi, Àn' èmi.
Rọ̀ ojò náà s' orí mi.

Má kọjá mi, Bàb' Olóore!
B' ẹ̀ṣẹ́ tilẹ̀ gb' ọkàn mi
Má ṣe fi mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n
Jẹ́ k' àánú Rẹ bá mi gbé.
Àn' èmi, Àn' èmi.
Rọ̀ ojò náà s' orí mi.

Mo há ti sùn nín' ẹ̀ṣẹ́ pẹ́?
Mo há bí O nínú pẹ́?
Mo há f' ọkàn mi f' ayé pẹ́?
Gbà mí, k' O dàríjì mi!
Àn' èmi, Àn' èmi.
Rọ̀ ojò náà s' orí mi.

Má kọjá mi Ẹ̀mí Mímọ́!
Wọ le là 'jú afọ́jú
Jẹ́rìí ìtóyẹ ti Jésù,
Sọ̀r' àlàáfíà sí mi,
Àn' èmi, Àn' èmi.
Rọ̀ ojò náà s' orí mi.