Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 193: F' Agbára Ọ̀run

Baptise Us Anew

F' agbára ọ̀run
Baptís wa l' ọ̀tún,
F' ìfẹ́ tú wa l' ara
Fà wá, Olúwa.

Ní 'rẹ̀lẹ̀ a bẹ̀ O,
Jésù Olúwa,
Fi ìfẹ́ àt' ẹ̀mí
Baptís wa lónìí.

Aláàyè ni wa
Àt' ẹni àìmọ́,
Jọ̀ọ́ sọ wa di mímọ́
Kúrò nín' ẹ̀ṣẹ́.

Ní 'rẹ̀lẹ̀ a bẹ̀ O,
Jésù Olúwa,
Fi ìfẹ́ àt' ẹ̀mí
Baptís wa lónìí.

Àdàbà Ọ̀run,
Jọ̀ọ́ sọ kalẹ̀ wá,
A tọrọ 'bùkún Rẹ
L' àánú sọ kalẹ̀.

Ní 'rẹ̀lẹ̀ a bẹ̀ O,
Jésù Olúwa,
Fi ìfẹ́ àt' ẹ̀mí
Baptís wa lónìí.

Gb' ohùn dídùn náà,
Tí ó t' ọ̀run wá!
'Wọ l' àyànní ọmọ mi
Tí 'nú mi dùn sí."

Àwa f' ìyìn fún
Ọ-'d'-àgùtàn ta à pa,
A fi ògo fún O,
Àmín àt' Àmín.