Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 191: Bàbá Fún Wa Ní Ná 'Yè Ni

Oh For That Flame Of Living Fire

Bàbá fún wa ní ná 'yè ni
T' ó jó n' n' àwọn èèyàn Mímọ́
Tí ó mú wọn lẹ́pà ọ̀run:
Ìbalẹ̀ ayà n' nú ewu.

Ẹ̀mí náà há dà, Olúwa
T' ó ṣe Abram l' ènìyàn Rẹ?
Tí ó yí ọkàn Paul padà,
T' ó sì fún un l' agbára ọ̀run.

Ẹ̀mí náà dà t' ó ti ń kọ́ ni
L' ọ̀nà Rẹ lát' ìrandíran?
T' ó mọ́lẹ̀ n' nú 'wé Isaiah,
T' ó sì farahàn nínú Psalm?

Oor'-ọ̀fẹ́ Rẹ há l' agbára
Bí ìgbà tí Elijah mọ̀?
'Gbàt' ògo hàn l' ojú Mose
Tàb' ìgbà Job' kọjá 'dánwò?

Rántí ọjọ́ wọn ni, Bàbá;
Gbé 'ṣẹ́ Rẹ dìde, Olúwa;
Báa sì ti gb' ọkàn wa sókè,
Wá tú Ẹ̀mí Rẹ s' orí wa.