Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 189: F' Ẹ̀mí Fún Wa, Jésù

Grant Us Thy Spirit Lord

F' Ẹ̀mí fún wa, Jésù,
'Gbàta á ń gbàdúà
Jẹ́ k' á le gb' ohùn Rẹ,
K' á sì gbọ́ràn,
A ń bọ f' àánú Krístì,
'Wọ j' Aláànú 'Wá sí gbogbo ọkàn
T' ó tọ O wá.

F' Ẹ̀mí fún wa, Jésù,
Àìní wa pọ̀; 'Wọ l' ó le 'bùkún ni,
Jọ̀ọ́ búkún wa;
Máa f' ọ̀rọ̀ òtítọ́
T' ìyè bò wa,
Tít' ìfẹ́ wa yóò pé
Nínú Krístì.

F' Ẹ̀mí fún wa, Jésù
Nísisìyí; Kọ́ wa láti máa rìn
Nípa 'gbàgbọ́;
'Gbà 'rè-jẹ wa bá pín,
Ṣe wa n' Tìrẹ
Jẹ́ kí a máa sìn O,
N' wájú 'tẹ́ Rẹ.