Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 187: Kí Olùràpadà Wa Tó
Our Blest Redeemer
Kí Olùràpadà wa tó
Dágbére ìkẹhìn,
Ó rán Olùtùnú sí wa
Tí ń bá wa gbé.
Ó wá pẹ̀lú iná ìyè,
Láti f' ọ̀nà hàn wa;
Ó wá pẹ̀l' agbár' afẹ́fẹ́
Àt' ìrẹ̀lẹ̀.
Ó dé, Ó mú 'wà-rere wá,
Àlejò Olóore;
'Gbàt' Ó bá r' ọkàn ìrẹ̀lẹ̀
Láti máa gbé.
Tìrẹ l' ohùn jẹ̀jẹ̀ t' a á ń gbọ́,
Ohùn kélékélé;
Tí ń bá ni wí, tí ń l' èrù lọ,
Tí ń sọ t' ọ̀run.
Gbogbo ìwà rere ta á ní,
Gbogbo ìṣẹ́gun wa
Gbogbo èrò ìwà mímọ́
Tìrẹ ni wọn.
Ẹ̀mí Mímọ́, Olùtùnú,
F' ìyọ̀nú bẹ̀ wa wò;
Jọ̀ọ́ ṣ' ọkàn wa n' ìbùgbé Rẹ,
K' ó yẹ fún O.