Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 183: Ní Orúkọ Jésù

At the Name of Jesus

Ní orúkọ Jésù,
Kí eékún wolé;
Gbogbo ahọ́n ni yóò
Pè E l' Olúwa,
Ìfẹ́ Bàbá ni pé
K' á pè E l' Olúwa;
Ní àtẹ́tẹ́kọ́ṣe
Oùn ni Ọ̀rọ̀ náà.

Nípa Rẹ ni a dá
Gbogb' ohun t' a à dá;
Gbogb' àwọn áńgẹ́lì,
Nínú ògo ńlá,
ìtẹ́ àt' ìjọba
Àwọn ìràwọ̀,
Oòrùn àt' oṣùpá;
Oùn l' ó dá wọn.

Síbẹ̀ ó wá s' ayé,
Ó di ènìyàn;
Láti gbà orúkọ
'Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Oùn ni Olùgbàlà,
Krístì Olúwa;
Ẹni tí 'yìn tọ́ sí
Jẹ́ k' á gbékèlé E.

Ṣe E l' Ọba l' ọkàn rẹ,
Jẹ́ k' Ó wẹ̀ ọ mọ́;
Gbogbo ìwà àìmọ́
Àt' àìṣòdodo,
Bèèrè ìrànwọ́ Rẹ,
Nígbà ìdánwò;
Múra nígbà gbogbo
Láti ṣe 'fẹ́ Rẹ.

Rántí, arákùnrin,
Jésù yìí tún ń bọ̀;
Nínú ògo Bàbá,
Pẹ̀l' áńgẹ́lì Rẹ.
Ó ń bọ̀ láti jọba
Ayé àt' ọ̀run;
Gbà náà gbogbo ọkàn
Yóò ṣe E ní Ọba.