Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 179: Mo Ń Ṣ' Ògo Nín' Àgbélébù
In The Cross Of Christ I Glory
Mo ń ṣ' ògo nín' àgbélébù
T' a a kàn Olùgbàlà mọ́;
Gbogbo 'mọ́lẹ̀ ìtàn mímọ́
K' ara wọn jọ s' orí rẹ̀.
'Gbàt' òòkún ayé yí mi ká,
T' ìrètí mi di òfo
Tèmi l' àgbélébù síbẹ̀
Ó ń tàn mọ́lẹ̀ pẹ̀l' ayọ̀.
Nígbà tí oòrùn ayọ̀ ń tàn
'Mọ́lẹ̀ ìfẹ́ s' ọ̀nà mi,
Dídán ẹwà àgbélébù
Fi kún ògo ọjọ́ náà.
Àgbélébù sọ ìrora
Àti àdùn di mímọ́;
Àlàáfíà púpọ̀ wà n' bẹ̀
Àt' ayọ̀ tí kò l' òpin.