Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 178: Ìwọ Ẹni T' Ojú Rẹ M' Ọkàn Mi Yọ̀
O Thou in Whose Presence
Ìwọ Ẹni t' ojú Rẹ m' ọkàn mi yọ̀
Ẹni mo ń ké pè n' gbà 'pònjú
'Tùnú mi lósàn-án àt' orin mi lórù
Ìrètí àt' ìgbàlà mi!
A gb' ohùn dídùn Rẹ b' ìró dùúrù ńlá
Ní inú òjìjì ikú;
Igi kedárì tẹríbà l' ẹsẹ̀ Rẹ
Ẹ̀ẹ́mí Rẹ mú afẹ́fẹ́ dùn.
Ọ̀rọ̀ Rẹ ń sàn jáde gẹ́gẹ́ bí omi.
Láti m' oore-ọ̀fẹ́ dàgbà
Kí àwọn kèfèrí le mọ 'gbàlà wọn,
Kí wọn le jẹ́ ìgbádùn Rẹ
Ó ń wò, ẹgbẹ̀gbẹ̀rún
áńgẹ́lì sì ń yọ̀,
Ogun ọ̀run sì ń gb' ọ̀rọ̀ Rẹ;
Ó sọ̀rọ̀, àní ọ̀rọ̀ ti àìlópin
Ní orin ìyìn s' Olúwa.