Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 176: Oókọ Kan Wà Tí Mo Fẹ́ Gbọ́
There Is A Name I Love To Hear
Oókọ kan wà tí mo fẹ́ gbọ́,
Mo fẹ́ máa kọ ọ́ l' orin;
Ó dùn bí orin l' etí mi
Oókọ t' ó dùn jù lọ.
Ó sọ ìfẹ́ Olùgbàlà,
T' ó kú láti gbà mi;
Ẹ̀ẹ̀tú pípé f' ẹ̀ṣẹ́.
Ó sọ t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ 'yẹbíyẹ̀.
Ó sọ t' ẹ̀rín tí Bàbá
Ń rín sí Ọmọ Rẹ yìí;
Nígbà yìí l' Ó ń m' ara mi yà,
Nínú àṣálẹ̀ yìí
Jésù, l' oókọ t' ó wù mí 'pọ̀,
Oókọ t' ó ń wù mí gbọ́;
Ìtóyẹ rẹ̀ jù sísọ lọ
Kò s' ọkàn t' ó le mọ̀.
'Mọ́lẹ̀ oókọ yìí yóò máa tàn
S' ọ̀nà t' ó l' ẹ̀gún yìí,
Yóò sì m' ọ̀nà náà dán fún mi
T' ó lọ s' ọ̀dọ̀ Jésù.