Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 175: Jí Ọkàn Mi F' Ayọ̀ Dìde

Awake My Soul in Joyful Lays

Jí ọkàn mi f' ayọ̀ dìde,
Kọrin 'yìn s' Olùgbàlà rẹ
Ó f' ẹ̀tọ́ bèèrè orin mi
Ìṣeun 'fẹ́ Rẹ ti pọ̀ tó!

Ó rí i, mo ṣubú sínú ẹgbẹ́,
Síbẹ̀ Ó fẹ́ mi l' àfẹ́tán:
Ó yọ mi nínú ẹgbẹ́ mi:
'Ṣeun 'fẹ́ Rẹ ti tóbi tó!

B' ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀tá,
Àti ayé ń dènà fún mi
Yóò mú mi là gbogbo wọn já;
'Ṣeun 'fẹ́ Rẹ tí n' ipa tó!

'Gbà 'yọnú dé, b' àwọ̀sánmọ̀
T' ó ṣú dúdú t' ó ń sàn àrá;
Ó dúró tì mí láàárín wọn
'Ṣeun 'fẹ́ Rẹ ti dára tó!

'Gbàt' Ọba ayé yìí bá dé,
Láti m' àwọn Tìrẹ rè 'lé,
N ó kọrin l' èbúté ayọ̀
Orin Ṣeun 'fẹ́ Rẹ láéláé.