Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 172: Ẹ Yìn Ẹni Mímọ́ Jùlọ
Praise To The Holiest In The Height
Ẹ yìn Ẹni Mímọ́ Jùlọ,
L' òkè àti n' ilẹ̀;
Ọ̀rọ̀ Rẹ gbogbo jẹ́ 'yànú,
Gbogb' ọ̀nà Rẹ dájú.
Ọgbọ́n Ọlọ́run ti pọ̀ tó!
Gbàt' ènìyàn ṣubú,
Adám' Kejì wá s' ojú 'jà,
Láti gbà wá sílẹ̀.
A, Ìfẹ́ ńlá! ẹran ara
T' ó mú Adám' kùnà,
Tún b' ọ̀tá jà ìjà l' ọ̀tún,
Ó jà, Ó sì ṣẹ́gun!
Ìdààmú Rẹ nínú ọgbà,
Àt' àgbélébù Rẹ,
Ń kọ́ wa k' á faradà ìyà,
K' á múra dé ikú.
Ẹ yìn Ẹni Mímọ́ jùlọ,
L' òkè àti n' ilẹ̀;
Ọ̀rọ̀ Rẹ gbogbo jẹ́ 'yànú,
Gbogb' ọ̀nà Rẹ dájú.