Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 17: Wá Sìn Olúwa Nínú Ẹwà Ìwà Mímọ́
O Worship The Lord In the Beauty of Holiness
Wá sìn Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́
Wolé fún Un, kó o sì k' òkìk' ọ̀go Rẹ̀;
Pẹ̀lú 'gbọ́ràn pípé àt' ìrẹ̀lẹ̀ t' ó dájú
Wá wólẹ̀ fún Un, kí o sì Júbà Rẹ̀.
Gbé erù àníyàn rẹ lé 'lẹ̀ lẹ́sẹ̀ Rẹ̀,
Yóò sì fún 'ra Rẹ̀ bá ọ gbé e dórí;
Yóò tú ọ nínú, yóò sì gbọ́ àdúrà rẹ,
Yóò tọ́ ṣiṣe rẹ b' ó títọ́ fún ọ.
Má bẹ̀rù láti wọ àgbàlá Rẹ̀,
Pẹ̀lú Ẹ̀bùn kíkún nínú àìní ọ̀rọ̀ rẹ;
Wá òótọ́ tó pé àti 'fẹ́ tó kún,
Ẹ̀bùn báyìí l' à ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ
Bá a tilẹ̀ m' ore wọ̀nyí wá ní ìtìjú,
Òun yóò gbà wọ́n l' orúkọ Rẹ̀ ọ̀wọ̀n;
Ayọ̀ òwúrọ̀ yóò dípò ẹkún alẹ́.
Ìrètí kíkún yóò dípò ẹ̀rù.