Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 169: Oníṣègùn Ńlá Wà Níhìn In
The Great Physician Now is Near
Oníṣègùn nlá wà níhìn in,
Jésù Abánidárò;
Ọ̀rọ̀ Rẹ mú ni lárayá,
Fẹ́tí sí ohùn Jésù.
Ìró dídùn l’ orin Seraf
Oókọ dídùn l’ ẹnu ènìyàn,
Orin t’ ó dùn jùlọ ni,
Jésù! Jésù! Jésù!
Ògo ni fún Ọd'-Àgùtàn
Mo gbà Jésù gbọ́ lónìí
Mo fẹ́ oókọ Olùgbàlà.
Mo fẹ́ orúkọ Jésù.
Ìró dídùn l’ orin Seraf
Oókọ dídùn l’ ẹnu ènìyàn,
Orin t’ ó dùn jùlọ ni,
Jésù! Jésù! Jésù!
Oókọ Jésù nìkan l' ó le
Èrù àt' ẹbi mi lọ;
Mo ti fẹ́ tó láti máa gbọ́
Oókọ Jésù 'yẹbíyẹ!
Ìró dídùn l’ orin Seraf
Oókọ dídùn l’ ẹnu ènìyàn,
Orin t’ ó dùn jùlọ ni,
Jésù! Jésù! Jésù!
Nígbà t' Ó bá dé pẹ̀l' adé,
Adé ìyè àt' ògo
A ó jókòó yí Ẹlẹ́dá ká
A ó sọ 'tàn ìràpadà.
Ìró dídùn l’ orin Seraf
Oókọ dídùn l’ ẹnu ènìyàn,
Orin t’ ó dùn jùlọ ni,
Jésù! Jésù! Jésù!