Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 168: Gbogbo Ayé, Gbé Jésù Ga

All Hail the Power

Gbogbo ayé, gbé Jésù ga,
Áńgẹ́l' ẹ wolé fún Un,
Áńgẹ́l' ẹ wolé fún Un,
Ẹ mú adé Ọba Rẹ wá,
Ṣe E l' Ọba,
l' Ọba, l' Ọba, l' Ọba
L' Ọba, l' Ọba, l' Ọba
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba

Ẹ̀yin ìran Israel t' a à yàn
Ìran t' a à yà s' ọ̀tọ̀
Ìran t' a à yà s' ọ̀tọ̀
Yìn Ẹni fún yín n' gbà l' ọ̀fẹ́
Ṣe E l' Ọba...

Gbogbo ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀,
Rántí 'bànújẹ́ yín,
Rántí 'bànújẹ́ yín;
Ẹ tẹ 'kògun yín s' ẹsẹ̀ Rẹ
Ṣe E l' Ọba...

Kí gbogbo orílẹ̀-èdè,
Ní gbogbo àgbáyé;
Ní gbogbo àgbáyé;
Kí wọn kí, kàbíyèsílẹ̀.
Ṣe E l' Ọba...

A bá le pẹ̀l' àwọn t' ọ̀run,
Láti máa júbà Rẹ,
Láti máa júbà Rẹ;
K' a báà le jọ jùmọ̀ kọrin
Ṣe E l' Ọba...