Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 167: Gbogbo Ayé, Gbé Jésù Ga
All Hail the Power
Gbogbo ayé, gbé Jésù ga,
Áńgẹ́l' ẹ wolé fún Un,
Ẹ mú adé Ọba Rẹ wá,
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba
Ẹ mú adé Ọba Rẹ wá,
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba
Ẹ̀yin ìran Israel t' a à yàn
Ìran t' a à yà s' ọ̀tọ̀
Yìn Ẹni fún yín n' gbà l' ọ̀fẹ́
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba
Yìn Ẹni fún yín n' gbà l' ọ̀fẹ́
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba
Kí gbogbo orílẹ̀-èdè,
Ní gbogbo àgbáyé;
Kí wọn kí, kàbíyèsílẹ̀.
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba
Kí wọn kí, kàbíyèsílẹ̀.
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba.
A bá le pẹ̀l' àwọn t' ọ̀run,
Láti máa júbà Rẹ;
K' a báà le jọ jùmọ̀ kọrin
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba
K' a báà le jọ jùmọ̀ kọrin
Ṣe E l' Ọba, àwọn Ọba.