Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 166: Àgọ́ Rẹ Ti Ní Ẹwà Tó
How Lovely Are Thy Dwellings
Àgọ́ Rẹ ti ní ẹwà tó,
Kò s' àríwó níbẹ̀!
Ìdàpọ̀ ọkàn tí ń pè O
Há ti ní ẹwà tó!
Wọn l' àfonífojì kọjá,
Àní àṣálẹ̀ ńlá,
Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ eléso,
T' omi púpọ̀ gbé wà!
Wọn ń rìn lát' ipa dé ipa,
Pẹ̀l' ayọ̀ oùn ẹrín,
Tít' ọkàn gbogbo yóò fi hàn
N' wájú Rẹ ní Sion.
Jésù tí 'ṣ' Oòrùn àt' Àsà,
Yóò fún wa ní ògo;
Gbogb' ohun rere l' ó wà fún
Àwọn tí ń rìn déédé.