Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 165: Ọkàn Àt' Ohùn Mi
My Hearts and Voice I Raise
Ọkàn àt' ohùn mi,
Ni n ó fi yìn Jésù
Kí gbogb' ayé yìn Mesaya:
Olúwa àgbáyé,
Nípa ọ̀rọ̀ Ẹni
T' a à dá ayé ní àdápẹ̀.
Ó wá bí ìránṣẹ́
Nínú awọ ẹ̀dá,
Ó sì tẹrí gbà ègún wa;
Ó tà 'jẹ̀ Rẹ sílẹ̀
Ó fi 'ra Rẹ rúbọ,
K' Ó le dá ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.
Ó jìndé b' Aṣẹ́gun,
Ó borí ọ̀tá Rẹ;
Ó sì kó wọn ní ìgbèkún;
Ó fọ́ ìjọba wọn,
Ó mú wọn jẹ́wọ́ pé,
Mesaya l' Ọba gbogb' ayé.
'Jọba Rẹ fẹ́rẹ̀ẹ́ dé,
K' á ṣe 'fẹ́ Rẹ l' ayé,
Gẹ́gẹ́ bí wọn ti ń ṣe l' ọ̀run;
Ẹni ṣá tó Jésù
Yóò sì rí ìràpadà
Yóò sì rí ìgbàlà ńlá Rẹ.