Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 164: Jésù Ayọ̀ Ọkàn Gbogbo
Jesus, Thou Joy of Loving Hearts
Jésù ayọ̀ ọkàn gbogbo,
Orísun 'yè, ìmọ́lẹ̀ wa,
Nín' ọ̀pọ̀ 'bùkún ayé yìí
Láìní 'tẹ́lọ́rùn: a tọ O wá.
Òtítọ́ Rẹ dúró láéláé,
'Wọ ń gb' àwọn tó ké pè O là.
Àwọn tí ó wá O, rí O,
N' bi gbogbo, nín' ohun gbogbo.
A tọ O wò, oúnjẹ ìyè,
A fẹ́ jẹ l' ara Rẹ títí;
A mu nínú Rẹ, Orísun,
Láti pa oùngbẹ ọkàn wa.
Oùngbẹ Rẹ ṣàá ń gbé ọkàn wa,
Níbikíbi t' ó wù k' á a wà,
'Gbàt' a bá rí O, àwa yọ̀,
A yọ̀ nígbà t' a á gbà O gbọ́.
Jésù, wá bá wa gbé títí,
Ṣe àkókò wa ní rere:
Lé òkùnkùn ẹ̀ṣẹ́ kúrò,
Tàn ìmọ́lẹ̀ Rẹ s' ayé wa.