Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 162: Jésù, Kìkì Ìrònú Rẹ

Jesus, The Very Thought Of Thee

Jésù, kìkì ìrònú Rẹ,
Fi ayọ̀ kún ọkàn;
Ṣùgbọ́n k' á rí O l' ó dùn jù
K' á simi lọ́dọ̀ Rẹ.

Ẹnu kò sọ, etí kò gbọ́,
Kò tí ọkàn wa rí;
Oókọ t' ó ṣọ̀wọ́n, t' ó dùn bí
Ti Jésù Olúwa.

Ìrètí ọkàn tí ń kàánú
Olóore ẹlẹ́ṣẹ̀;
Ó ṣeun f' àwọn tí ń wá O,
Àwọn t' ó rí O yọ̀.

Ayọ̀ wọn, ẹnu kò le sọ,
Ẹ̀dá kò le rọ́yìn
Ìfẹ́ Jésù, b' ó ti pọ̀ tó,
Àwọn Tìrẹ l' ó mọ̀.

Jésù, 'Wọ máa jẹ́ ayọ̀ wa,
'Wọ ṣàá ni ère wa;
Máa jẹ́ ògo wa nísìyí,
Àti títí láéláé.