Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 161: Ẹ Yìn Ín, Ẹ Yìn Ín

Praise Him! Praise Him!

Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín Jésù Olùràpadà wa,
'Ayé ẹ kọrin, ṣ' ọ̀fẹ́ 'yànú Rẹ;
Ẹ kí l' ẹ̀yìn olórí áńgẹ́lì nín' ògo
Ẹ f' ọlá àt' ipa f' orúkọ Rẹ.
B' Olùṣọ́-Àgùtàn, yóò ṣọ́ àwọn ọmọ Rẹ
Yóò gbé wọn l' apá Rẹ ní gbogb' ọjọ́.

Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín,
Ẹ sọ̀rọ̀ títóbi ńlá Rẹ;
Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín,
nínú orin ayọ̀.

Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín, Jésù Olùràpadà wa,
'Tór' ẹ̀ṣẹ́ wa Ó jìyà Ó sì kú;
Oùn l' àpáta wa ìrètí ìgbàlà wa;
Ẹ kí Jésù t' a a kàn m' àgbélébù
Sọ 'yìn Jésù, t' Ó rù ìbànújẹ́ wa,
Ìfẹ́ àìníwọ̀n, ìfẹ́ ìyànu.

Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín,
Ẹ sọ̀rọ̀ títóbi ńlá Rẹ;
Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín,
nínú orin ayọ̀.

Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín, Jésù Olùràpadà wa,
Àwọn 'lẹ̀kùn ọ̀run ń kọ hosana;
Jésù Olùgbàlà jọba títí láéláé,
Dé E l' adé, Wòlíì, Alúfáà, Ọba.
Krístì ń bọ̀ wá, b' aṣẹ́gun lór' ayé yìí,
Ipa àt' ògo fún orúkọ Rẹ.

Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín,
Ẹ sọ̀rọ̀ títóbi ńlá Rẹ;
Ẹ yìn Ín, ẹ yìn Ín,
nínú orin ayọ̀.