Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 160: Jésù Yóò Jọba Ní Gbogbo Ibití A Bá Le Rí Oòrùn
Jesus Shall Reign Where'er The Sun
Jésù yóò jọba ní gbogbo
Ibití a bá le rí oòrùn;
Jọba Rẹ yóò tàn kárí ayé
Tít' oṣùpá kò ní wọ̀ mọ́.
Gbogbo oníruúrú èdè
Yóò jùmọ̀ kọrin ìfẹ́ Rẹ
Àwọn ọmọdé yóò jẹ́wọ́
Pé 'bùkún wọn t' ọ̀dọ̀ Rẹ wá.
'Bùkún pọ̀ níbi t' Oùn jọba
A ń tú àwọn ondè sílẹ̀,
Àwọn aláàrẹ̀ rí 'simi,
Aláìní sì ń rí 'bùkún gbà.
Kí gbogb' àwọn ẹ̀dá dìde,
Kí wọn f' ọlá fún Ọba wa;
K' áńgẹ́lì sọ kalẹ̀ t' àwọn t' orin
Kí gbogb' ayé jùmọ̀ gbé 'rin.