Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 157: Ilẹ̀ Kan Wà Tí Ó Kún F' Oyìn
There is a Land of Corn and Wine
Ilẹ̀ kan wà t' ó kún f' oyìn,
Ayọ̀ rẹ̀ yóò sì jẹ́ t' èmi
Ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ ayọ̀ ń tàn,
Tór' òòkún ayé ti kọjá.
Ilẹ̀ ayọ̀, ilẹ̀ dídán,
Mo fẹ́ wà lórí òkè náà,
Kí n máa wò ọ̀kun dídán náà
Àt' ìbùgbé t' a á ti pèsè,
Kí n le rí i lẹ́tí èbúté
Ọ̀run àt' ilé mi láéláé.
Olúwa mi yóò bá mi rìn;
Èyí yóò jẹ́ 'dàpọ̀ dídùn.
Oùn yóò fà mí lọ́wọ́ jẹ̀jẹ̀
Ní ilẹ̀ ayọ̀ dídán náà.
Ilẹ̀ ayọ̀, ilẹ̀ dídán,
Mo fẹ́ wà lórí òkè náà,
Kí n máa wò ọ̀kun dídán náà
Àt' ìbùgbé t' a á ti pèsè,
Kí n le rí i lẹ́tí èbúté
Ọ̀run àt' ilé mi láéláé.
Oòrùn dídùn nín' afẹ́fẹ́,
Yóò máa t' ara igi jáde,
Àti odòdó tí kì í rẹ̀.
Níb' odò ìyè ń sàn títí.
Ilẹ̀ ayọ̀, ilẹ̀ dídán,
Mo fẹ́ wà lórí òkè náà,
Kí n máa wò ọ̀kun dídán náà
Àt' ìbùgbé t' a á ti pèsè,
Kí n le rí i lẹ́tí èbúté
Ọ̀run àt' ilé mi láéláé.
Afẹ́fẹ́ yóò sì kún fún
Ìró orin ayọ̀ dídùn
Gbàt' àwọn áńgẹ́lì yóò máa kọ
Nínú orin ìràpadà.
Ilẹ̀ ayọ̀, ilẹ̀ dídán,
Mo fẹ́ wà lórí òkè náà,
Kí n máa wò ọ̀kun dídán náà
Àt' ìbùgbé t' a á ti pèsè,
Kí n le rí i lẹ́tí èbúté
Ọ̀run àt' ilé mi láéláé.