Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 155: 'Jọba Rẹ Dé Ọlọ́run

Thy Kingdom Come O God

Jésù, 'jọba Rẹ dé,
Kí àṣẹ Rẹ bẹ̀rẹ̀
F' ọ̀pá irin Rẹ fọ́
Ìwà ìpá ẹ̀ṣẹ́.

'Jọba ìfẹ́ Rẹ dà
Mímọ́ àlàáfíà?
Nígbà wo n' ìríra
Yóò d'òpin bí t' ọ̀run?

'Gbàwo l' àkókò náà
T' ogun kì yóò sí mọ́,
T' ẹ̀ṣẹ́ oun ìrẹ̀jẹ̀
Yóò sá lọ n' wájú Rẹ?

Yóò dìde Olúwa,
Wá, l' agbára ńlá Rẹ
Fún ojú àwa tí
Ń ṣ' àfẹ̀rí Rẹ l' ókun.

Ènìyàn ń kẹ́gàn Rẹ
'Kòòkó ń p' àgbo Rẹ run
Ọ̀pọ̀ ìwà 'tìjú
Ń fihàn pé 'fẹ́ ń tutù.

Òkùnkùn wà síbẹ̀
Ní ilẹ̀ kèfèrí,
'Ràwọ̀ oòrọ̀, dìde;
Dìde, má ṣe wọ̀ mọ́.