Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 154: Ayé Kọ Olúwa Wa
Our Lord Is Now Rejected
Ayé kọ Olúwa wa,
kò sì gbà ní tirẹ̀;
Ọ̀pọ̀ ni ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
Àwọn díẹ̀ l' ó gbà Á;
Láìpẹ́ yóò dé n' nú ògo,
Ìgbà ìjọba Rẹ ń bọ̀ wá nígboosẹ̀.
Ọjọ́ ìjọba Rẹ ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá nígboosẹ̀,
Gb' Olúwa yóò dé n' agbára
Àt' ògo lát' òkè
Ìrí ògo náà yóò mú 'nú
Àwọn àṣọ̀nà dùn,
L' ọjọ́ ológo Rẹ t' ó ń bọ̀ nígboosẹ̀.
Àwọn ọ̀run y' óò dán,
Ṣùgbọ́n àwọn mímọ́
Yóò dán jù wọn lọ, bí Kríst'
Yóò ti ṣe wọn l' ọ̀ṣọ́ọ́
Ẹwà Olùgbàlà wa
Yóò mú k' ojú sọ̀ọ̀kún,
L' ọjọ́ ológo Rẹ t' ó ń bọ̀ nígboosẹ̀.
Ọjọ́ ìjọba Rẹ ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá nígboosẹ̀,
Gb' Olúwa yóò dé n' agbára
Àt' ògo lát' òkè
Ìrí ògo náà yóò mú 'nú
Àwọn àṣọ̀nà dùn,
L' ọjọ́ ológo Rẹ t' ó ń bọ̀ nígboosẹ̀.
Ìrora wa y' óò d' òpin,
A kì yóò dẹ́ṣẹ̀ mọ́,
A ó gbàgbé ìbànújẹ́,
A ó sì wà nín' ayọ̀;
Ayọ̀ n' n' Olùràpadà,
Bí a ó ti sún mọ́ Ọ,
L' ọjọ́ ológo Rẹ t' ó ń bọ̀ nígboosẹ̀.
Ọjọ́ ìjọba Rẹ ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá nígboosẹ̀,
Gb' Olúwa yóò dé n' agbára
Àt' ògo lát' òkè
Ìrí ògo náà yóò mú 'nú
Àwọn àṣọ̀nà dùn,
L' ọjọ́ ológo Rẹ t' ó ń bọ̀ nígboosẹ̀.
Jẹ́ kí àwọn tí ń rètí
Bíbọ̀ Rẹ múra dè Ẹ
Nípa Ìyàsímímọ́
Oún rìn 'nà tóóró
Ní kíkó ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ
Àwọn tí O kú fún,
Fún ọjọ́ ológo tí ń bọ̀ nígboosẹ̀.
Ọjọ́ ìjọba Rẹ ń bọ̀ wá,
Ó ń bọ̀ wá nígboosẹ̀,
Gb' Olúwa yóò dé n' agbára
Àt' ògo lát' òkè
Ìrí ògo náà yóò mú 'nú
Àwọn àṣọ̀nà dùn,
L' ọjọ́ ológo Rẹ t' ó ń bọ̀ nígboosẹ̀.