Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 152: Ìjọ Tí Ń Dúró Pẹ́

The Church Has Waited Long

Ìjọ tí ń dúró pẹ́,
Láti rí Olúwa;
Ó sì wà bákan náà síbẹ̀,
Kò s'àlàbàrò fún un.

Yóò ti pẹ́ tó Bàbá
Olóòótọ́, Olóore!
'Wọ kì yóò kọ 'yà, omijé
Àt' ẹ̀jẹ́ ìjọ Rẹ.

A ń fẹ́ gbọ́ ohùn Rẹ,
A ń fẹ́ f' ojú kan Ọ;
K' á le gbà adé àt' ògo,
B' a á ti ń gbà oore Rẹ.

Jọ̀ọ́ wá m' ẹ̀ṣẹ́ kúrò,
Àt' ẹ̀gàn, àt' ẹ̀ẹ̀rí;
K' O sọ ayé òṣì wa yìí
D' ayé rere Tìrẹ.