Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 151: Lójúkójú

Face to face

Yóò há ti dùn tó láti rí
Krístì mi lójúkójú,
'Gbàtí mo bá rí I pẹ̀l' ayọ̀
Jésù Krístì t' ó kú fún mi

Lójúkójú l' èmi ó rí I,
L' òk' ọ̀run gígá jù lọ;
Lójúkójú l' èmi ó rí I,
Nín' ògo Rẹ̀ nígboosẹ̀

Báibái nínú àwòjìjì
Ni mo ń rí I nísisìyí;
Ṣùgbọ́n ọjọ́ ìbùkún ń bọ̀
Tí a ó rí ògo Rẹ̀

Lójúkójú l' èmi ó rí I,
L' òk' ọ̀run gígá jù lọ;
Lójúkójú l' èmi ó rí I,
Nín' ògo Rẹ̀ nígboosẹ̀

Ayọ̀ wa yóò há ti pọ̀ tó
'Gbà 'bànújẹ́ wa fò lọ;
'Gbàt' ọ̀nà wa bá di títọ́,
T' ohun tí ó sìn yóò hàn

Lójúkójú l' èmi ó rí I,
L' òk' ọ̀run gígá jù lọ;
Lójúkójú l' èmi ó rí I,
Nín' ògo Rẹ̀ nígboosẹ̀

A! àkókò ìbùkún yìí,
'Gbà tí n ó rí i, tí n ó mọ̀.
Olùgbàlà lójúkójú
Jésù Kríst' t' Ó fẹ́ mi bẹ́ẹ̀.

Lójúkójú l' èmi ó rí I,
L' òk' ọ̀run gígá jù lọ;
Lójúkójú l' èmi ó rí I,
Nín' ògo Rẹ̀ nígboosẹ̀