Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 150: 'Gbàt' Ó Bá Dé
When He Cometh, When He Cometh
'Gbàt' Ó bá dé, 'gbàt' Ó bá dé
Láti ṣír' oṣó Rẹ;
Gbogb' oṣó Rẹ ìyebíye,
Àwọn tí Ó fẹ́ E!
Bí ìràwọ̀ òwúrọ̀,
Wọn ń ṣ' adé Rẹ l' oṣóo
Ẹwà wọn ó yọ púpọ̀
Ẹwà f' adé Rẹ.
Yóò kó o jọ, yóò kó o jọ
Oṣó ìjọba Rẹ;
Àwọn mímọ́, àwọn dídàn,
Àwọn tí Ó fẹ́ E!
Bí ìràwọ̀ òwúrọ̀,
Wọn ń ṣ' adé Rẹ l' oṣóo
Ẹwà wọn ó yọ púpọ̀
Ẹwà f' adé Rẹ.
Àwọn ẹwé, àwọn ẹwé
T' ó fẹ́ Olùgbàlà:
Ni oṣó Rẹ ìyebíye,
Àwọn tí Ó fẹ́ E.
Bí ìràwọ̀ òwúrọ̀,
Wọn ń ṣ' adé Rẹ l' oṣóo
Ẹwà wọn ó yọ púpọ̀
Ẹwà f' adé Rẹ.