Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 15: Mo Fẹ́ Mọ̀ Síi Nípa Jésù

More about Jesus I would Know

Mo fẹ́ mọ̀ síi nípa Jésù,
Ki n f' oore Rẹ̀ hàn elòmíì,
Ki n r' ẹ̀kún ìgbàlà Rẹ̀ gbà,
Ìfẹ́ Ẹni t' ó kú fún mi.

Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Ki n r' ẹ̀kún ìgbàlà Rẹ̀ gbà,
Ìfẹ́ Ẹni t' ó kú fún mi.

Jẹ́ kí n kọ́ sí i nípa Jésù,
Ki n kọ́ sí i nípa ìfẹ́ Rẹ̀;
Ẹ̀mí ọ̀run s' olùkọ́ mi,
Fi ìfẹ́ ti Krístì hàn mí.

Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Ki n r' ẹ̀kún ìgbàlà Rẹ̀ gbà,
Ìfẹ́ Ẹni t' ó kú fún mi.

K' èmi máa bá Olúwa mi
Sọ̀rọ̀ lát' inú ọ̀rọ̀ Rẹ̀,
Ki n máa gb' ohùn Rẹ̀ 'gbà gbogbo.
Ki n f' ọ̀rọ̀ ìyè ṣe t' èmi.

Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Ki n r' ẹ̀kún ìgbàlà Rẹ̀ gbà,
Ìfẹ́ Ẹni t' ó kú fún mi.

Mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jésù,
Tire ni gbogb' ọ̀rọ̀ í ṣe;
Ìbísí 'jọba Rẹ̀ dájú,
Ọm'-Aládé Àlááfíà.

Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Mo fẹ́ mọ̀ Jésù sí i,
Ki n r' ẹ̀kún ìgbàlà Rẹ̀ gbà,
Ìfẹ́ Ẹni t' ó kú fún mi.