Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 149: Gbà Tí Ìpè Olúwa Bá Dún
When The Trumpet of The Lord Shall Sound
Gbà tí ìpè Olúwa bá dún
t' ayé yóò sì fò lọ,
Tí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ títun yóò sì dé;
Nígbà tí àwọn ọmọ ìgbàlà
bá péjọ l' òkè,
Tá a bá sì p' orúkọ níbẹ̀,
N ó wà n' bẹ̀.
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
Nípa oore-ọ̀fẹ́ nìkan,
N ó wà ń bẹ̀.
Lo oòrọ̀ ọjọ́ t' àwọn okú nínú
Kríst' yóò jìndé
Tí wọn yóò sì pín n' nú ògo àjíǹdé,
'Gbà tí àwọn àyànfẹ́ yóò
péjọ sí odé ọ̀run,
Tá a bá sì p' orúkọ l' ohùn-un
N ó wà n' bẹ̀.
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
Nípa oore-ọ̀fẹ́ nìkan,
N ó wà ń bẹ̀.
Jẹ́ kí a fi gbogbo àkókò
wa ṣiṣẹ́ f' Olúwa,
Jẹ́ kí a rọ̀yìn ìfẹ́ ìyànu Rẹ
Nígbà tí a bá sì parí
ire ìjẹ wa l' ayé,
Tá a bá sì p' orúkọ l' ohùn-un
N ó wà n' bẹ̀.
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
'Gbàt' á a bá p' orúkọ l' ohùn-un
Nípa oore-ọ̀fẹ́ nìkan,
N ó wà ń bẹ̀.