Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 148: Gbà 'Wọ Onídàjọ́ Bá Dé
When Thou My Righteous Judge
'Gbà 'wọ Onídàjọ́ bá dé
Láti m' àwọn Tìrẹ lọ 'lé,
N ó hà wà l' àárín wọn?
A ó hà r' ẹ̀kòlò lásán yìí,
Tí ẹ̀rù ikú kò yẹ bá
Ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ?
Mo fẹ́ bá wọn péjọ níhìn-ín
Láti máa wolé l' ẹsẹ̀ Rẹ,
Bí mo tilẹ̀ ṣ' àìyé;
Ara mi hà le gbà bá a bá
Fi orúkọ t' èmi s' ẹ̀yìn,
N' ìgbà t' Ó bá ń pè wọn
K' àánú Rẹ má jẹ́ k' ó rí bẹ́ẹ̀,
Olúwa, ṣe 'bi 'sádí mi,
L' ọjọ́ t' ó tóbi yìí;
Jẹ́ kí n gb' ohùn 'dàríjì Rẹ,
Láti lé àìgbàgbọ́ mi lọ,
Má sì jẹ́ kí n ṣubú.
Jẹ́ kí n wà láàrín èèyàn Rẹ,
'Gbàt' ìpè Áńgẹ́lì bá dún,
Láti rí ojú Rẹ;
Èm' ó kọrin l' ohùn gòòrò,
'Gbà 'búgbé Rẹ l' òkè bá ń hó
Pẹ̀l' orin ìgbàlà.