Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 147: Ọlọ́run! Kín Ni Mo Rí Yìí?
Great God, What Do I see and Hear!
Ọlọ́run! Kín ni mo rí yìí?
Òpin ohun gbogbo dé
Onídàjọ́ aráyé yọ,
Ó gunwá nínú ògo!
Ìpè dún, àwọn ìbòjì
Tú okú inú wọn jáde!
Múra, lo kọ Ọ́, ọkàn mi.
Àwọn tí Kríst' ni yóò kó ǹdé
'Gbàt' ìpè kẹyìn bá dún
Wọn ó lọ kọ Ọ́ l' àwọ̀sánmọ̀
Wọn ó fi ayọ̀ yí I ká:
Kò s' ẹ̀rù tí yóò b' ọkàn wọn;
Ojú Rẹ yóò tàn 'mọ́lẹ̀ sí
Àwọn tí ó múra dé E.
Ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ t' ó kú fún
Ẹ̀rù, ń wò ìrúnú Rẹ
Wọn ó dìde l' àtí rí i pé
Ẹ̀rù wọn kò jà mọ́ nnkan
Ọjọ́ oòr' ọ̀fẹ́ ti kọjá
Wọn d' rò n' wájú 'tẹ́ pẹ̀l' ẹ̀rù
Láì múra dé bíbọ̀ Rẹ.
Onídàjọ́ nlá! 'wájú Rẹ
L' á f' ìrẹ̀lè ń gbàdúrà;
F' ìfẹ́ nlá Rẹ dáàbòbò wá,
Là 'gbà ewu 'kẹyìn jà
Jẹ́ k' á gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ
Ní ọjọ́ ìdánwò wa yìí
Kí a báà múra dé Ọ.