Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 145: Gbà Jésù Bá Dé Láti Pín Ère

When Jesus Comes to Reward His Servants

Gbà Jésù bá dé láti pín ère,
B' ó j' ọ̀sán tàbí l' órù.
Yóò hà bá wa níbìt' á gbé ń ṣọ́'nà,
Pẹ̀l' àtùpà wa tí ń tàn?

A le wí pé a múra tán, ara,
Láti lọ s' ilé dídàn?
Yóò hà bá wa níbìt' á gbé ń ṣọ́'nà
Dúró, títí Olúwa yóò fi dé?

Bí l' òwúrọ̀ ní àfẹ́mójúmọ́
Ni yóò pè wá lọ̀kọ̀ọ̀kan
Gbàt' á f' Olúwa l' ẹ̀bùn wa padà
Yóò hà dáhùn pé, "Ó ṣeun?"

A le wí pé a múra tán, ara,
Láti lọ s' ilé dídàn?
Yóò hà bá wa níbìt' á gbé ń ṣọ́'nà
Dúró, títí Olúwa yóò fi dé?

A hà ṣòótọ́ nínú ìlànà Rẹ?
A ṣa ipa wa gbogbo?
Bí ọkàn wa kò bá dá wa l' ẹ̀bí,
A ó ní sìmí ògo.

A le wí pé a múra tán, ara,
Láti lọ s' ilé dídàn?
Yóò hà bá wa níbìt' á gbé ń ṣọ́'nà
Dúró, títí Olúwa yóò fi dé?

Ìbùkún ni fún àwọn 'tí ń ṣ' ọ́nà,
Wọn ó pín nín' ògo Rẹ,
Bí Ó bá dé l' ọ̀sán-an tàbí l' órù,
Yóò hà bá wa ní 'ṣọ́nà?

A le wí pé a múra tán, ara,
Láti lọ s' ilé dídàn?
Yóò hà bá wa níbìt' á gbé ń ṣọ́'nà
Dúró, títí Olúwa yóò fi dé?